ILUPEJU EKITI, PT.10 (Live)-K1 De Ultimate

ILUPEJU EKITI, PT.10 (Live)

时间:2025-02-08

    使用手机浏览器「扫一扫」

    在手机上保存,获得更好体验

标签
歌词

Òun ló sọ bẹ́ẹ̀ Rasida ìyá Rasidi

Èdè Ìbàdàn ló fi pè é Ìbàdàn proper

Rasidatu o (ah Rasidatu o)

Ìyá oní Rasidi (Rasidatu o)

Ìyá Ìbàdàn ló ní n kí ẹ (Rasidatu o)

Mo kí ẹ Abbey (Abbey mi)

Regina baby o (sweetie kan baby)

Regina baby o o o (sweetie kan baby)

(Igbo lyrics)

Ìjẹ̀bú thank you, thank you, thank you

(Igbo lyrics)

Ìyá mi Àdùnní o jagunjagun nìyá mi

Èèyàn kan ò tó bẹ̀ kó ta mí láyà o Hajia Àdùnní (jagunjagun Àdùnní o)

Ìyá mi Àdùnní, jagunjagun Àdùnní o, abiamọ Àdùnní o

Kiníkan ò mà ní ṣe ẹ́ o ṣá ma rìn, máa yàn fanda

(jagunjagun l’Àdùnní o)

Irọ́ l’ẹlẹ́gàn ń pa (wọn ò lè jẹ)

Èké l’ẹlẹ́gàn ń ṣe (wọn ò lè jẹ)

Bíọ́dún yìí ló ń jó o Abbey

Abbey South africa

Ọ̀túnba Fẹ́mi ní kí n máa kí ẹ o

Ọ̀túnba Fẹ́mi Fáladé Atáyéṣe of Ẹgbẹ́dá

Bọ́bagúnwà gbogbo t’Ìbèshè land Aláṣẹ FAMFEM

Ọmọ ìgbàgbọ́ Èkìtì awo tí Figo cap ó ní kí n kí ẹ

Abbey South Africa Ọ̀túnba ní n kí ẹ

Ọ̀túnba Fẹ́mi Fáladé Atáyéṣe gbogbo Ẹgbẹ́dá

Tó o bá dé Ẹgbẹ́dá kó o bá mi kí Kábíèsí

Laka mi Ọba Ẹlẹ́gbẹ́dá

Ọ̀túnba Fáladé Bọ́bagúnwà gbogbo t’Ìbèshè Land

Aláṣẹ FAMFEM èèyàn Bíọ́dún mi Abbey

Abbey South Africa ní n dúpẹ́

Fẹ́mi Fáladé (Fẹ́mi Fáladé)

Fẹ́mi Fáladé (Fẹ́mi Fáladé)

Fẹ́mi Fáladé (Fẹ́mi Fáladé)

Atáyéṣe Ẹgbẹ́ (Atáyéṣe Ẹgbẹ́dá)

Atáyéṣe Ẹgbẹ́ (Atáyéṣe Ẹgbẹ́dá)

Fẹ́mi Fáladé (Fẹ́mi Fáladé)

B’íjó bá wà lẹ́sẹ̀ (o ò ya jẹ́ ká jọ jó)

B’íjó bá wà lẹ́sẹ̀ (o ò ya jẹ́ ká jọ jó)

B’íjó bá wà lẹ́sẹ̀ (o ò ya jẹ́ ká jọ jó)

Ọ̀túnba Fẹ́mi Fáladé ẹ kú àdúrótì

Abbey ní n dúpẹ́ Abbey South Africa ó ń dúpẹ́

Bọ́bagúnwà gbogbo t’Ìbèshè Land ìná ò ní tán owó ẹ Àmín o

Ọ̀túnba Fẹ́mi Fáladé mo mà mí ẹ kí ẹ Àyìndé

Bó o bá délé bá mi kí Ẹlẹ́gbẹ́dá Kábíèsí Laka

Aláyélúwà l’Ẹ́gbẹ́dá àti oníbèshè ó ń gbọ́ nílé

Fẹ́mi Fáladé (Fẹ́mi Fáladé)

Ìtọ̀pá mo kí ẹ kí ẹ (Fẹ́mi Fáladé)

Ìtọ̀pá ètùtù mo kí ẹ kí ẹ (Fẹ́mi Fáladé)

Yí ó da fún ọ tí ó pọ̀ (Fẹ́mi Fáladé)

Láti Ìlúpéjú lọ sí (lọ sí Tafa)

Ìtọ̀pá ètùtù ilé Fẹ́mi (Fẹ́mi Fáladé)

Èèyàn Bíọ́dún Abíọ́dún mi Abbey (Fẹ́mi Fáladé)

Gbogbo yín ẹ kú àdúrótì a dúpẹ́

Abbey, awo Ọlámilékan Gàjí mi

Ayédáadé mi Gàjí

Abdulganiyu

Gbogbo yín ẹ ṣé mo dúpẹ́

Motúnrayọ̀ láti South Africa yìí o ṣé

Ko ṣe Ìtọ́jú Ẹmẹ́ka bọ̀bọ́

Ẹmẹ́ka Wisdom Túnráyọ̀ ní n kí ẹ

Túnráyọ̀ aṣẹ́wó láti South Africa Ajé á máa wá

Àdúà ẹ á gbà o ṣé o Túnráyọ̀ baby

Ẹmẹ́ka gbogbo yín ẹ kú àdúrótì

Abbey mi ń dúpẹ́ dúpẹ́

Ọmọdé yìí Túnráyọ̀ baby

Láti South Africa Túnráyọ̀ mo dúpẹ́ dúpẹ́ dúpẹ́ dúpẹ́ dúpẹ́

Túnráyọ̀ yìí ṣe ọmọlúàbí o

Gbogbo yín ẹ kú àdúrótì Abíọ́dún láti South Africa

O ṣé mo dúpẹ́ Ẹmẹ́ka

Ẹ̀yin ti South, ẹ káàbọ̀ sí ìlú Nàìjíríà

Ẹ̀yin ti South Africa ẹ káàbọ̀ sí Nàìjíríà mo kí i yín

Túnráyọ̀ mi (Túnráyọ̀ mi)

Ṣẹ́wo ṣẹ́wo ni Túnráyọ̀ (Túnráyọ̀ mi)

Èèyàn tó bá ń ṣẹ’wó, tó ń ṣe currency exchange

Kíni ká a pè ẹ́?

Kíni ká a pè é? Aṣẹ́wó ni

Túnráyọ̀ ni (Túnráyọ̀ ni)

Láti south Africa ajé á máa wọgbá

Emeka Wisdom ọkọ Mariam Baby

Bosman lọkọ Mariam point of correcting o tún bẹ̀rẹ̀ Ganiyu

Mariam aya Bosman

Emeka Emeka Wisdom máa gbọ́ bí n ṣe ń wí

Ẹ̀yin ti South Africa nílùú Nàìjíríà mo ki yín

Mariam Baby aya Bosman Túnráyọ̀ mo kí ẹ

Túnráyọ̀ mi (Túnráyọ̀ ni)

Túnráyọ̀ mi (Túnráyọ̀ ni)

Lerato South Africa

Lerato ní South Africa

Gbogbo yín ẹ káàbọ̀ sílé

Ẹ káàbọ̀ sí Nàìjíríà o ṣeun Lerato mi

Túnráyọ̀ mi (Túnráyọ̀ mi)

Emeka Wisdom mo kí ẹ kí ẹ (Túnráyọ̀ mi)

Mariam ìyàwó Bosman (Túnráyọ̀ mi)

Àwọn ti South Africa ní Nàìjíríà (Túnráyọ̀ ni)

Emeka Emeka Wisdom (Túnráyọ̀ ni)

Èèyàn t’Emeka Wisdom (Túnráyọ̀ ni)

Odogwu Odogwu 1

Emeka Wisdom (Emeka Wisdom mi)

Emeka Wisdom (Emeka Wisdom ni)

Ẹ̀yin ti South Africa ẹ kú àdúrótì Bíọ́dún

Èèyàn Tó bá ń yọ́’lẹ̀ ẹ́ dà

Ohun burúkú á máa yọ irúu wọn ṣe

Abbey, á ṣe wọ́n ní kọ̀rọ̀ á tún ṣe wọ́n ní gbangba

Ẹní bá ń yọ́nú sí ẹ

Ẹní bá ń yọ́nú sí ẹ o

O sure jù ìyọ́nú Ọlọ́hun Ọba

Ìyọ́nú Ọlọ́hun Ọba

Ìyọ́nú Ọlọ́hun Ọba

Ìyọ́nú Ọlọ́hun Ọba (òhun ni wọ́n ó máa rí)

Shínà Quadri máa gbọ́ bí n ṣe ń wí

Aláṣẹ Mediagrills

Sunny Olúwatọ́ba

Kéhìndé Bọ̀súyì

O ṣé mo dúpẹ́ o Shínà Quadri náà náwó

展开显示全部歌词