Ayọ̀délé (Live)-K1 De Ultimate

Ayọ̀délé (Live)

时间:2024-12-09

    使用手机浏览器「扫一扫」

    在手机上保存,获得更好体验

标签
歌词

Ó ń múnú mi dùn o (Ó ń mú’nú mi dùn o)

Èèyàn tani?

Èèyàn ti Bournvita mi Ayọ̀ délé ọ́rẹ

Àkókó Akúmarì Àkókó

Àkànní mi Bournvita o

Àkànní, ta l’ajá wọn ń pakuru mọ́

(Ta lọ̀pọ̀lọ́ wọn ń dẹrù’ba?)

Ọkọ Semia Bàsírá mi Àbọ̀lọrẹ

Ọlá bàbá Rodiya, Bàbá Rodiya Oyindamola

Bàbá ìkókó mi Junior

Àkànní Akuma mi ọkọ Àbọ̀lọre

Òun náà ní’lù, Ah ah

Ṣé gbogbo owó ìlù yìí ni mo ti gbà

Olúayé Fújì Arábámbí

Kàmọ́rù ẹ kà ń da jẹ ni, ẹ̀ ń da jẹ ah

Anyway, tó bá fẹ́ wọ inú rẹ́kọ̀dù, gbogbo owó ẹ̀ ní ń máa gbà arábámbí

Èdìdí kìí di barà o o o

Bournvita, Akeem, Èdìdí kìí di barà o

Àkànní, ọkọ Semia Bàsírá mi ọkọ t’Àbọ̀lọrẹ

Èèyàn dáadáa lèèyàn mi

Ọ̀rẹ́ dáadáa lèèyàn mi

Ayọ̀délé Àkànní Bournvita Bíbíire

Wò mí dáadáa wo èèyàn mi

Èèyàn dáadáa lèèyàn mi Ayọ̀délé Àkànní Bournvita

Bíbíire bíbíire kò Ṣé fowó rà nílé wa

Àyìndé Ọmọ́gbọ́láhàn mi

Ẹni tí wọ́n bá ṣẹ́ ìlù fún, ìhun tó dùn mí

Àwọn onílù tí ò mọ̀, bí wọ́n bá náwó na arábámbí

Ọ̀rọ̀ mi ni wọ́n o máa sọ ìlù wọn

Ìlù tí àwa ń kọ àwa ló yé

Bí mo ṣe ń kọrin, (àṣẹ Olúwa ni)

Àní bí mo ṣe ń lùlù (àṣẹ Olúwa ni)

Bournvita Àkànní, bí mo ṣe ń kọrin mi (àṣẹ Olúwa ni)

Dende bí mo ṣe ń lùlù (àṣẹ Olúwa ni)

Awo ṣá ni gbòǹgbò èdè kó tó yọ ewé

Ẹ tún bá mi tún ìlù yẹn lù arábámbí

(Drum rendition)

Gbogbo àwọn ìlù yẹn ìkan ò jọ̀kan

Níṣe ni gbogbo ẹ̀ dùn, set by set

Ẹ gbọ́ ná, ṣé ẹ ṣe ìlù fún dúdú?

Ọba àwọn àjòjì, ẹ ẹ̀ ṣe ìlù fun

Ẹ ẹ̀ ṣe ìlù fún Easy koboko, ah

Ó di méjì, ah

Ẹ ẹ̀ ṣe ìlù fún secretary Akoko A

Ówó yìí, owó easy Koboko, ẹgbẹ́ ló mu fún

Ikú ò kí ń jẹun ẹni kó pani, ẹ ya lọ ṣèlù fun

Ìlù easy Koboko Arábámbí

Owó ẹgbẹ́, ẹ má d’owó yìí pọ̀ Àyìndé Ọmọtógbọ́láhàn owó ìlù ni

Àkànní adé (Àkànní adé)

Ọkọ Semia Basira (Àkànní adé)

Ọkọ Semia Basira (Àkànní adé)

Aisha má ì lọ (Aisha má ì lọ)

Lará baby má ì lọ (baby má ì lọ)

Àyìndé mò ń bọ̀ o (arábámbí)

Easy Koboko

展开显示全部歌词